1 Chronicles 26:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu ìdílé Heburoni, Haṣabaya ati ẹẹdẹgbẹsan (1,700) àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alágbára ni wọ́n ń bojútó àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ OLUWA ati iṣẹ́ ọba,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu awọn ọmọ Hebroni, Hasabiah ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, ẽdẹgbẹsan li awọn alabojuto Israeli nihahin Jordani niha iwọ-õrun, fun gbogbo iṣẹ Oluwa, ati fun ìsin ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hébírónì: Háṣábíà àti àwọn ìbátan Rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀san (17,000) ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Ísírẹ́lì, ìhà ìwọ̀ oòrùn Jórólánì fún gbogbo iṣẹ́ OLÚWA àti fún iṣẹ́ ọba.