1 Chronicles 26:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu ìdílé Heburoni, Jerija ni baba ńlá gbogbo wọn. (Ní ogoji ọdún tí Dafidi dé orí oyè, wọ́n ṣe ìwádìí nípa ìran Heburoni, wọ́n sì rí àwọn ọkunrin tí wọ́n lágbára ninu ìran wọn ní Jaseri ní agbègbè Gileadi).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu awọn ọmọ Hebroni ni Jerijah olori, ani ninu awọn ọmọ Hebroni, gẹgẹ bi idile ati iran awọn baba rẹ̀. Li ogoji ọdun ijọba Dafidi, a wá wọn, a si ri ninu wọn, awọn alagbara akọni enia ni Jaseri ti Gileadi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níti àwọn ará Hébírónì, Jéríyà jẹ́ olóyè wọn gẹ́gẹ́ bí ìwé ìrántí ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní ti ìdílé wọn. Ní ọdún kẹrin ìjọba Dáfídì, a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí, àwọn ọkùnrin alágbára láàrin àwọn ará Hébíronì ni a rí ní Jáṣérì ní Gílíádì.