1 Chronicles 26:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ọba, yan òun ati àwọn arakunrin rẹ̀, tí gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa ó lé ẹẹdẹgbẹrin (2,700) alágbára, láti jẹ́ alámòójútó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase nípa gbogbo nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun ati àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, jẹ ẹgbã o le ẽdẹgbẹrin: gbogbo wọn jẹ awọn olori baba ti Dafidi ọba fi ṣe olori lori awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, fun gbogbo ọ̀ran ti Ọlọrun ati ti ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéríyà ní ẹgbàáméjì, àti ọgọ́rin méje ìbátan, tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbára àti olórí àwọn ìdilé ọba Dáfídì sì fi wọ́n ṣe àkóso lórí àwọn ará Reúbẹ́nì àwọn ará Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè fun gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jọ mọ́ ti Ọlọ́run àti fún ọ̀ràn ti ọba.