1 Chronicles 26:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣemaaya, àkọ́bí Obedi Edomu, bí ọmọ mẹfa, àwọn ni olórí ninu ìdílé wọn nítorí pé alágbára eniyan ni wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun Ṣemaiah ọmọ rẹ̀ li a bi awọn ọmọ ti nṣe olori ni ile baba wọn: nitori alagbara akọni enia ni nwọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ Rẹ̀ Ṣémáíà ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé bàbá a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára.