1 Chronicles 27:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn wọnyi ni àwọn olórí ìdílé ati olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati olórí ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ aṣojú ọba ní gbogbo ìpínlẹ̀ ní oṣooṣù, títí ọdún yóo fi yípo ni wọn máa ń yan ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000) eniyan, tí wọn ń pààrọ̀ ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NJẸ awọn ọmọ Israeli nipa iye wọn, eyini ni, awọn olori baba, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn ijoye wọn ti nsìn ọba ni olukuluku ọ̀na li ẹgbẹgbẹ, ti nwọle ti si njade li oṣoṣù ni gbogbo oṣù ọdun, jẹ́ ẹgbã mejila.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọrọrún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣoṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin (24,000) ọkùnrin.