1 Chronicles 27:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Balogun tí ó wà fún oṣù kejila ni Helidai ará Netofati, láti inú ìran Otinieli; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olori ogun kejila fun oṣù kejila ni Heldai ara Netofa, ti Otnieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Hélídáì ará Nétófátì láti ìdílé Ótíníélì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.