1 Chronicles 27:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joabu, ọmọ Seruaya, bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn eniyan, ṣugbọn kò parí rẹ̀. Sibẹsibẹ ibinu OLUWA wá sórí Israẹli nítorí rẹ̀; nítorí náà, kò sí àkọsílẹ̀ fún iye àwọn ọmọ Israẹli ninu ìwé ìtàn ọba Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ si ikà wọn, ṣugbọn kò kà wọn tan, nitori ibinu ṣubu lu Israeli nitori na; bẹ̃ni a kò fi iye na sinu iwe Kronika ti Dafidi ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù ọmọ Ṣérúyà bẹ̀rẹ̀ sí ní kàwọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Ísírẹ́lì nipaṣẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọọ́ sínu ìwé ìtàn ayé ti ọba Dáfídì.