1 Chronicles 27:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lori awọn iṣura ọba ni Asmafeti ọmọ Adieli wà: ati lori iṣura oko, ni ilu, ati ni ileto, ati ninu odi ni Jonatani ọmọ Ussiah wà:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áṣímáfétì ọmọ Ádíélì wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jónátanì ọmọ Úṣíà wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìlètò àti àwọn ilé ìṣọ́.
Recommended Reading