1 Chronicles 27:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jonatani, arakunrin baba Dafidi ọba, ni olùdámọ̀ràn nítorí pé ó ní òye, ó sì tún jẹ́ akọ̀wé. Òun ati Jehieli, ọmọ Hakimoni, ní ń ṣe àmójútó àwọn ọmọ ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jonatani ẹgbọn Dafidi pẹlu ni ìgbimọ ọlọgbọ́n enia ati akọwe: ati Jehueli ọmọ Hakmoni wà pẹlu awọn ọmọ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jónátanì, arákùnrin Dáfídì jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. Jéhíélì ọmọ Hákímónì bojútó àwọn ọmọ ọba.