1 Chronicles 27:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dodai, láti inú ìran Ahohi, ni olórí ìpín ti oṣù keji, iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lori ẹgbẹ ti oṣù keji ni Dodai ara Ahohi, ati ẹgbẹ tirẹ̀; Mikloti pẹlu nṣe balogun: ẹgbã mejila li o wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dódáì ará Áhóhì; Míkílótì jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).