1 Chronicles 27:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Asaheli, arakunrin Joabu, ni balogun fún oṣù kẹrin. Sebadaya, ọmọ rẹ̀, ni igbákejì rẹ̀. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Ásáhélì arákùnrin Jóábù: ọmọ Rẹ̀ Ṣébádáyà jẹ́ arọ́pò Rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.