1 Chronicles 28:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi bá fún Solomoni ní àwòrán tẹmpili náà tí wọ́n fi ọwọ́ yà, ati ti àwọn ilé mìíràn tí yóo kọ́ mọ́ tẹmpili, ati ti àwọn ilé ìṣúra rẹ̀, àwọn yàrá òkè, àwọn yàrá ti inú, ati ti yàrá ìtẹ́ àánú;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Dafidi fi apẹrẹ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ ti iloro, ati ti ile rẹ̀, ati ti ibi iṣura rẹ̀, ati ti iyara-òke rẹ̀, ati ti gbangan inu rẹ̀ ati ti ibi ibujoko ãnu,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Dáfídì fún Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ní ètò fún èbúté ilé OLÚWA náà, kíkọ́ ọ Rẹ̀, àwọn yàrá ìṣúra Rẹ̀, ibi òkè Rẹ̀, àwọn ìyẹ̀wù Rẹ̀ àti ibi ìpètù sí Rẹ̀.