1 Chronicles 28:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi tún fún un ní ìwé ètò pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn inú ilé OLUWA, ti àwọn ohun èlò fún ìsìn ninu ilé OLUWA;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niti ipin awọn alufa pẹlu ati ti awọn ọmọ Lefi, ati niti gbogbo iṣẹ ìsin ile Oluwa, ati niti gbogbo ohun èlo ìsin ni ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé OLÚWA àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn Rẹ̀.