1 Chronicles 28:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ètò iṣẹ́ ati pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ninu tẹmpili ni a ti ṣe fínnífínní. Àwọn tí wọ́n mọ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ yóo wà pẹlu rẹ, bákan náà, àwọn olórí ati gbogbo eniyan Israẹli yóo wà lábẹ́ àṣẹ rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, ipin awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, wà pẹlu rẹ fun oniruru ìsin ile Ọlọrun: iwọ ni pẹlu rẹ oniruru enia, ọlọkàn fifẹ, ẹniti o ni oye gbogbo iṣẹ fun oniruru iṣẹ: pẹlupẹlu awọn ijoye ati gbogbo awọn enia wà pẹlu rẹ fun gbogbo ọ̀ran rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìpín àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì ti ṣetan fún gbogbo iṣẹ́ ilé OLÚWA. Gbogbo ọkùnrin tí ó ní ìfẹ́ sí i tí ó sì ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn yóò gbọ́ràn sí gbogbo àṣẹ rẹ.”