1 Chronicles 28:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn, Ọlọrun sọ fún mi pé, kì í ṣe èmi ni n óo kọ́ ilé fún òun, nítorí pé jagunjagun ni mí, mo sì ti ta ẹ̀jẹ̀ pupọ sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun mi pe, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitori ologun ni iwọ, o si ti ta ẹ̀jẹ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé: Ìwọ kò gbodò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀sílẹ̀.