1 Chronicles 28:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sibẹsibẹ OLUWA Ọlọrun Israẹli yàn mí ninu ilé baba mi láti jọba lórí Israẹli títí lae; nítorí pé ó yan ẹ̀yà Juda láti ṣe aṣaaju Israẹli. Ninu ẹ̀yà Juda, ó yan ilé baba mi, láàrin àwọn ọmọ baba mi, ó ní inú dídùn sí mi, ó fi mí jọba lórí gbogbo Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Ọlọrun Israeli si yàn mi lati inu gbogbo ile baba mi lati jẹ ọba lori Israeli lailai: nitori ti o ti yàn Juda li olori; ati ninu ile Juda, ile baba mi: ati larin awọn ọmọ baba mi o fẹ mi lati jẹ ọba gbogbo Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Síbẹ̀ OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì, títí láé. Ó yan Júdà gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Júdà, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.