1 Chronicles 28:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, bí ó bá ti pinnu láti máa pa òfin ati ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nisinsinyii.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu emi o fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ lailai, bi o ba murale lati ṣe ofin mi ati idajọ mi bi li oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fi ìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí.