1 Chronicles 28:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, lójú gbogbo ọmọ Israẹli, lójú ìjọ eniyan OLUWA, ati ní etígbọ̀ọ́ Ọlọrun wa, mò ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ máa pa gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, kí ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín baà lè máa gbé ilẹ̀ yìí títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsìn yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí OLÚWA, àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa: Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin OLÚWA Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé.