1 Chronicles 29:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ọba sọ fún àpéjọpọ̀ àwọn eniyan pé, “Solomoni ọmọ mi, ẹnìkan ṣoṣo tí Ọlọrun yàn, ó kéré, kò tíì ní ìrírí, iṣẹ́ náà sì tóbi pupọ, nítorí ààfin náà kò ní wà fún eniyan, bíkòṣe fún OLUWA Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
DAFIDI ọba si wi fun gbogbo ijọ enia pe, Solomoni ọmọ mi, on nikan ti Ọlọrun ti yàn, jẹ ọmọde o si rọ̀, iṣẹ na si tobi: nitori ti ãfin na kì iṣe fun enia, ṣugbọn fun Ọlọrun Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ọba Dáfídì sọ fún gbogbo àpéjọ pé: “Ọmọ mi Sólomónì, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, ṣì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye. Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún OLÚWA Ọlọ́run.