1 Chronicles 29:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣugbọn, kí ni mo jẹ́, kí sì ni àwọn eniyan mi jẹ́, tí a fi lè mú ọrẹ tí ó pọ̀ tó báyìí wá fún Ọlọrun tọkàntọkàn? Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ninu ohun tí o fún wa ni a sì ti mú wá fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn tali emi, ati kili awọn enia mi, ti a fi le ṣe iranlọwọ tinutinu bi iru eyi? nitori ohun gbogbo ọdọ rẹ ni ti wá, ati ninu ohun ọwọ rẹ li awa ti fi fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n Ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè fi sílẹ̀ tinútínú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.