1 Chronicles 29:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, Ọlọrun wa, tìrẹ ni gbogbo ohun tí a mú wá, láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni wọ́n sì ti wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Ọlọrun wa, gbogbo ohun ọ̀pọlọpọ yi ti awa ti pèse silẹ lati kọ ile fun ọ fun orukọ rẹ mimọ́, lati ọwọ rẹ wá ni, ati gbogbo rẹ̀ jẹ tirẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run wa tí fi gbogbo pípọ̀ yìí tí àwa ti pèṣè fún kíkọ́ ilé OLÚWA fun orúkọ, mímọ́ Rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo Rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀.