1 Chronicles 29:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi mọ̀ pẹlu, Ọlọrun mi, pe iwọ ndan ọkàn wò, iwọ si ni inudidún si ododo. Bi o ṣe ti emi, ninu ododo ọkàn mi li emi ti fi tinutinu ṣe iranlọwọ gbogbo nkan wọnyi; ati nisisiyi pẹlu ayọ̀ ni mo ti ri awọn enia rẹ ti o wá nihin, lati fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsìn yìí èmi ti ríi pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́.