1 Chronicles 29:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti sa ipá tèmi láti pèsè oríṣìíríṣìí nǹkan sílẹ̀ fún ilé OLUWA: wúrà fún àwọn ohun tí a nílò wúrà fún, fadaka fún àwọn ohun tí a nílò fadaka fún, idẹ fún àwọn ohun tí a nílò idẹ fún, irin fún àwọn ohun tí a nílò irin fún, pákó fún àwọn ohun tí a nílò pákó fún, lẹ́yìn náà, òkúta ìkọ́lé, òkúta olówó iyebíye, àwọn òkúta tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, ati mabu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu gbogbo ipa mi ni mo ti fi pèse silẹ fun ile Ọlọrun mi, wura fun ohun ti wura, ati fadakà fun ti fadakà, ati idẹ fun ti idẹ, irin fun ti irin, ati igi fun ti igi; okuta oniki ti a o tẹ̀ bọ okuta lati fi ṣe ọṣọ, ati okuta oniruru àwọ, ati oniruru okuta iyebiye, ati okuta marbili li ọ̀pọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lu gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, òjíá fún ti òjíá, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ Rẹ̀, (túríkúóṣè) òkúta lóríṣíríṣí, àmọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkuta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀.