1 Chronicles 29:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keji, wọ́n fi ẹgbẹrun akọ mààlúù rú ẹbọ sísun sí OLUWA, ati ẹgbẹrun àgbò, ati ẹgbẹrun ọ̀dọ́ aguntan, pẹlu ọrẹ ohun mímu ati ọpọlọpọ ẹbọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si ru ẹbọ si Oluwa, nwọn si ru ẹbọ sisun si Oluwa, li ọjọ keji lẹhin ọjọ na, ẹgbẹrun akọmalu, ẹgbẹrun àgbo, ẹgbẹrun ọdọ-agutan, pẹlu ọrẹ mimu wọn, ati ẹbọ miran li ọ̀pọlọpọ fun gbogbo Israeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí OLÚWA, wọ́n sì rú ẹbọ ọrẹ ṣíṣun sí i: ẹgbẹ̀rún kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì.