1 Chronicles 29:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n jẹ, wọ́n sì mu níwájú Ọlọrun ní ọjọ́ náà pẹlu ayọ̀ ńlá. Wọ́n tún fi Solomoni, ọmọ Dafidi, jẹ ọba lẹẹkeji. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba ní orúkọ OLUWA, Sadoku sì ni alufaa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si jẹ nwọn si mu niwaju Oluwa li ọjọ na pẹlu ayọ̀ nla. Nwọn si tun fi Solomoni ọmọ Dafidi jọba li ẹ̃keji, a si fi ororo yàn a li ọba, ati Sadoku li alufa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú OLÚWA ní ọjọ́ náà. Nígbà náà wọ́n yan Sólómonì ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú OLÚWA láti ṣe olórí àti Ṣádókù láti ṣe àlùfáà.