1 Chronicles 29:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ati àwọn ohun èlò mìíràn tí àwọn oníṣẹ́ ọnà yóo lò: wúrà fún àwọn ohun èlò wúrà, ati fadaka fún àwọn ohun èlò fadaka. Nisinsinyii, ninu yín, ta ló fẹ́ fi tinútinú ṣe ìtọrẹ, tí yóo sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí fún OLUWA?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wura fun ohun èlo wura, ati fadakà fun ohun èlo fadakà, ati fun oniruru iṣẹ nipa ọwọ awọn ọlọnà. Tani si nfẹ loni lati yà ara rẹ̀ si mimọ fun Oluwa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún orísìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípaṣẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣíiríṣí iṣẹ́. Níṣinṣìn yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará Rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí OLÚWA?”