1 Chronicles 3:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni gbogbo awọn ọmọ Dafidi, laika awọn ọmọ àle rẹ̀, ati Tamari arabinrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dáfídì yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Támárì sì ni arábìnrin wọn.