1 Chronicles 4:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹsira bí Jeteri, Meredi, Eferi, ati Jaloni. Meredi fẹ́ Bitia, ọmọbinrin Farao. Wọ́n bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu ati ọmọkunrin meji: Ṣamai ati Iṣiba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ọmọ Esra ni Jeteri, ati Meredi, ati Eferi, ati Jaloni: on si bi Miriamu, ati Ṣammai, ati Iṣba baba Eṣtemoa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ésírà: Jétẹ́rì, Mérédì, Éférì àti Jálónì. Ọ̀kan lára àwọn aya Mérédì sì bí Míríámù, ṣámáì àti Íṣíbà baba Éṣítémóà.