1 Chronicles 4:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Hesekaya, ọba Juda wà lórí oyè, àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi lọ sí Meuni, wọ́n ba àgọ́ àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ jẹ́, wọ́n pa wọ́n run títí di òní, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilẹ̀ tiwọn, nítorí pé koríko tútù pọ̀ níbẹ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn, dé li ọjọ Hesekiah ọba Juda, nwọn si kọlu agọ wọn, ati pẹlu awọn ara Mehuni ti a ri nibẹ, nwọn si bà wọn jẹ patapata titi di oni yi, nwọn si ngbe ipò wọn: nitori koriko mbẹ nibẹ fun agbo ẹran wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin tí a kọ orúkọ Rẹ̀ sókè wà ní ọjọ́ Hésékíà ọba Júdà àti àwọn ibùgbé wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Máhúnì ẹni tí ó wà níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátapáta. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ ẹ̀rí títí di òníyìí. Nígbà náà wọ́n sì ń gbé ní iye wọn, nítorí pé koríko wà fún àwọn agbo ẹran wọn.