1 Chronicles 4:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹẹdẹgbẹta (500) ninu àwọn eniyan Simeoni ló lọ sí òkè Seiri; àwọn olórí wọn ni: Pelataya, Nearaya, Refaaya, ati Usieli, lára àwọn ọmọ Iṣi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Omiran ninu wọn, ani ninu awọn ọmọ Simeoni, ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin, lọ si òke Seiri, nwọn ni Pelatiah, ati Neariah, ati Refaiah ati Ussieli, awọn ọmọ Iṣi li olori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Síméónì, sin pẹ̀lú Pélátíà, Néáríà, Réfáíà àti Úsíélì, àwọn ọmọ Íṣì, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Ṣéírì.