1 Chronicles 5:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NJẸ awọn ọmọ Reubeni, akọbi Israeli, (nitori on li akọbi; ṣugbọn, bi o ti ṣepe o ba ẹní baba rẹ̀ jẹ, a fi ogun ibi rẹ̀ fun awọn ọmọ Josefu ọmọ Israeli: a kì yio si ka itan-idile na gẹgẹ bi ipò ibi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí Ísírẹ́lì. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ẹní baba Rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí.