1 Chronicles 5:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, àwọn ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ní ẹgbaa mejilelogun ati ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (44,760) akọni ọmọ ogun tí wọ́n ń lo asà, idà, ọfà ati ọrun lójú ogun, tí wọ́n gbáradì fún ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ninu awọn ọkunrin alagbara ti nwọn ngbé asà ati idà, ti nwọn si nfi ọrun tafà, ti nwọn si mòye ogun, jẹ ọkẹ meji enia o le ẹgbẹrinlelogún o di ogoji, ti o jade lọ si ogun na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé aṣà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn o le ẹgbẹ̀rinlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà.