1 Chronicles 5:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si ràn wọn lọwọ si wọn, a si fi awọn ọmọ Hagari le wọn lọwọ, ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu wọn: nitoriti nwọn kepè Ọlọrun li ogun na, on si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn: nitoriti nwọn gbẹkẹ wọn le e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hágárì lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí ti wọn képe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.