1 Chronicles 5:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, Ọlọrun ta Pulu ọba Asiria ati Tigilati Pileseri ọba Asiria, nídìí láti gbógun ti ilẹ̀ náà; wọ́n bá kó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọn ń gbé ìhà ìlà oòrùn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ Hala, Habori, Hara, ati ẹ̀bá odò Gosani títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun Israeli rú ẹmi Pulu ọba Assiria soke, ati ẹmi Tiglat-pilneseri ọba Assiria, on si kó wọn lọ, ani awọn ọmọ Rubeni ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, o si kó wọn wá si Hala, ati Habori, ati Hara, ati si odò Goṣani, titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ru ẹmi Púlù ọba Ásíríà sókè, ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ó sì kó wọn wá sí Hálà, àti Hábórì, àti Hárà, àti sí ọ̀dọ̀ Gósánì; títí dí òní yìí.