1 Chronicles 6:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
àwọn ni wọ́n ń kọ orin ninu Àgọ́ Àjọ títí tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA parí ní Jerusalẹmu; àṣegbà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si nfi orin ṣe isin niwaju ibugbe agọ ajọ, titi Solomoni fi kọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu tan: nwọn si duro ti iṣẹ óye wọn gẹgẹ bi ipa wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin ńiwájú Àgọ́ ìpàdé títí tí Ṣólómónì fi kọ́ ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n se iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.