1 Chronicles 6:49 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun ati lórí pẹpẹ turari; àwọn ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ninu ibi mímọ́ jùlọ, tí wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose, iranṣẹ Ọlọrun là sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ nrubọ lori pẹpẹ ẹbọ sisun, ati lori pẹpẹ turari, a si yàn wọn si gbogbo iṣẹ ibi mimọ́-jùlọ, ati lati ṣe ètutu fun Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ti pa li aṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Árónì àti àwọn ìran ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ọrẹ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a se ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti paláṣẹ.