1 Chronicles 6:62 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìlú mẹtala ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Geriṣomu ní ìdílé ìdílé lára àwọn ìlú ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Baṣani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun awọn ọmọ Gerṣomu ni idile wọn, lati inu ẹ̀ya Issakari, ati inu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati lati inu ẹ̀ya Manasse ni Baṣani, ilu mẹtala.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.