1 Chronicles 6:78 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní ìkọjá Jọdani níwájú Jẹriko, wọ́n fún wọn ní Beseri tí ó wà ní ara òkè, ati Jahasa,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì rékọjá Jódánì ìlà oòrùn Jẹ́ríkò wọ́n gba Bésérì nínú ihà Jáhíṣáhì,