1 Chronicles 7:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jediaeli; àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé ní ilé baba wọn ati akọni jagunjagun ninu ìran wọn tó ẹẹdẹgbaasan-an ó lé igba (17,200).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn wọnyi ọmọ Jediaeli, nipa olori awọn baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbãjọ o le ẹgbẹfa ọmọ-ogun, ti o le jade lọ si ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọmọ Jédíádì jẹ́ olórí ìdátan Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tadínlógún-ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetan láti jáde lọ sí ogun.