1 Chronicles 7:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Makiri fẹ́ iyawo kan ará Hupi, ati ọ̀kan ará Ṣupimu. Orúkọ arabinrin rẹ̀ ni Maaka. Orúkọ ọmọ rẹ̀ keji ni Selofehadi; tí gbogbo ọmọ tirẹ̀ jẹ́ kìkì obinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Makiri si mu arabinrin Huppimu, ati Ṣuppimu li aya, orukọ arabinrin ẹniti ijẹ Maaka,) ati orukọ ekeji ni Selofehadi: Selofehadi si ni awọn ọmọbinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mákírì sì mú ìyàwó láti àárin àwọn ará Hípímù àti Ṣúpímù. Orúkọ arábìnrin Rẹ̀ a má a jẹ́ Máákà. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a má a jẹ́ Ṣélóféhádì, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.