1 Chronicles 7:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Tola ni: Usi, Refaaya, Jerieli, Jahimai, Ibisamu ati Ṣemueli, àwọn ni baálé ninu ìdílé Tola, baba wọn, akikanju jagunjagun ni wọ́n ní àkókò wọn. Ní ayé Dafidi ọba, àwọn akikanju jagunjagun wọnyi jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹta (22,600).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ọmọ Tola; Ussi, ati Refaiah, ati Jerieli, ati Jamai, ati Jibsamu ati Samueli, awọn olori ile baba wọn, eyini ni ti Tola: akọni alagbara enia ni wọn ni iran wọn; iye awọn ẹniti o jẹ ẹgbã mọkanla o le ẹgbẹta li ọjọ Dafidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Tólà: Húsì, Réfáíáhì, Jéríélì, Jámáì, Jíbísámù àti Ṣámúẹ́lì Olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dáfídì, àwọn ìran ọmọ Tólà tò lẹ́sẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ẹgbẹ̀ta (22,600).