1 Chronicles 7:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká. Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati leti ilu awọn ọmọ Manasse, Betṣeani, ati ilu rẹ̀, Taanaki ati ilu rẹ̀, Megiddo ati ilu rẹ̀, Dori ati ilu rẹ̀. Ninu awọn wọnyi li awọn ọmọ Josefu, ọmọ Israeli, ngbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Mánásè ni Bétí ṣánì, Tánákì, Mógídò àti Dórì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò Rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.