1 Chronicles 7:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ni ìran Aṣeri, wọ́n jẹ́ baálé baálé ni ìdílé baba wọn, àṣàyàn akọni jagunjagun, ati olórí láàrin àwọn ìjòyè. Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n tó ogun jà ninu wọn, ní ìdílé ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtala (26,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Aṣeri, awọn olori ile baba wọn, aṣayan alagbara akọni enia, olori ninu awọn ijoye. Iye awọn ti a kà yẹ fun ogun, ati fun ijà ni idile wọn jẹ, ẹgbã mẹtala ọkunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Áṣérì olórí ìdílé, àwọn okùnrin tí a yàn àwọn ògbóyà jagunjagun àti àwọn adarí tí ó dúró sinsin. Iye àwọn ọkùnrin tí ó setan fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti se kọ ọ́ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.