1 Chronicles 8:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ jagunjagun, tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lókìkí. Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ̀ pọ̀. Aadọjọ ni wọ́n, ara ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni gbogbo wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Ulamu si jẹ alagbara akọni ọkunrin, tafatafa, nwọn si li ọmọ pupọ ati ọmọ ọmọ adọjọ. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Benjamini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Úlámù jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin márùndínlọ́gọ́jọ ní gbogbo Rẹ̀. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Bẹ́ńjámínì.