1 Chronicles 9:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìran wọn; a kọ wọ́n sinu ìwé Àwọn Ọba Israẹli. A kó àwọn ẹ̀yà Juda ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni nítorí pé wọ́n ṣe alaiṣootọ sí Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si ka iye gbogbo Israeli ni idile idile wọn; si kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli: Juda li a si kó lọ si Babiloni nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo Ísírẹ́lì ni a kọ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì. Àwọn ènìyàn Júdà ni a kó ní ìgbẹ̀kùn lọ sí Bábílónì nítorí àìsòótọ́ wọn.