1 Chronicles 9:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣalumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora ati àwọn ará ilé baba rẹ̀. Gbogbo ìdílé Kora ni alabojuto iṣẹ́ ìsìn ninu tẹmpili ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti jẹ́ alabojuto Àgọ́ OLUWA ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣálúmì ọmọ kórè ọmọ Ébíásáfì, ọmọ kórà, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ Rẹ̀. Láti ìdílé Rẹ̀ (àwọn ará kórà) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìlóró ẹnu ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ à bá wọlé ibùgbé OLÚWA.