1 Chronicles 9:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi ni alabojuto àwọn ohun èlò ìjọ́sìn, iṣẹ́ wọn ni láti máa fún àwọn tí wọ́n ń lò wọ́n, ati láti gbà wọ́n pada sí ipò wọn, kí wọ́n sì kà wọ́n kí wọ́n rí i pé wọ́n pé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé OLÚWA; wọn a má a kàá nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde.