1 Chronicles 9:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi kan wà fún orin kíkọ ninu tẹmpili, wọ́n jẹ́ baálé baálé ninu ẹ̀yà Lefi, ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu tẹmpili ni àwọn ń gbé, wọn kì í bá àwọn yòókù ṣiṣẹ́ mìíràn ninu tẹmpili, nítorí pé iṣẹ́ tiwọn ni orin kíkọ tọ̀sán-tòru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi si li awọn akọrin, olori awọn baba awọn ọmọ Lefi, nwọn kò ni iṣẹ ninu iyara wọnni; nitori ti nwọn wà lẹnu iṣẹ wọn lọsan ati loru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Léfì dúró nínú àgọ́ ilé OLÚWA, wọn kò sì se lára isẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń se isẹ́ náà lọ́sán, lóru.