1 Corinthians 1:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará, mo fi orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi bẹ̀ yín, gbogbo yín, ẹ fohùn ṣọ̀kan, kí ó má sí ìyapa láàrin yín. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí èrò yín sì papọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si bẹ̀ nyin, ará, li orukọ Oluwa wa Jesu Kristi, ki gbogbo nyin mã sọ̀rọ ohun kanna, ati ki ìyapa ki o máṣe si ninu nyin; ṣugbọn ki a le ṣe nyin pé ni inu kanna, ati ni ìmọ kanna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé kí gbogbo yín fohùnsọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyàpá láàrin yín, àtipé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.