1 Corinthians 10:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORI emi kò fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀, ara, bi gbogbo awọn baba wa ti wà labẹ awọsanma, ti gbogbo wọn si là okun já;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arakùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú ihà. Ọlọ́run samọ̀nà wọn nípa rírán ìkùúkù ṣíwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi òkun pupa já.